Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Weights: Must be just

11 ẹsẹ · 19 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Must be just

  1. “ ‘Ẹ má ṣe lo òsùwọ̀n èké, nígbà tí ẹ bá ń díwọ̀n yálà nípa òsùwọ̀n ọ̀pá, òsùwọ̀n ìwúwo tàbí òsùwọ̀n onínú.

  2. Ẹ jẹ́ olódodo pẹ̀lú àwọn òsùwọ̀n yín òsùwọ̀n ìtẹ̀wọ̀n, òsùwọ̀n wíwúwo, òsùwọ̀n ìyẹ̀fun àti òsùwọ̀n nǹkan olómi yín ní láti jẹ́ èyí tí kò ní èrú nínú. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti.

  3. Má ṣe ní oríṣìí ìtẹ̀wọ̀n méjì tó yàtọ̀ sí ara wọn nínú àpò rẹ, ọ̀kan wúwo àti ọ̀kan fífúyẹ́.

  4. Má ṣe ní oríṣìí ìwọ̀n méjì tí ó yàtọ̀ sí ara wọn ní ilé è rẹ: ọ̀kan fífẹ̀, ọ̀kan kékeré.

  5. O gbọdọ̀ ní ìtẹ̀wọ̀n àti òsùwọ̀n pípé àti ti òtítọ́ nítorí náà kí ìwọ kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ.

  6. Olúwa kórìíra òsùwọ̀n èké, ṣùgbọ́n òsùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀.

  7. Òdínwọ̀n àti òsùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa; gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.

  8. Ìwọ̀n èké àti òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ Olúwa kórìíra méjèèjì.

  9. Olúwa kórìíra òdínwọ̀n èké. Òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.

  10. Ǹjẹ́ ìṣúra ìwà búburú ha wà ní ilé ènìyàn búburú síbẹ̀, àti òsùwọ̀n àìkún tí ó jẹ́ ohun ìbínú?

  11. Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́ pẹ̀lú òsùwọ̀n búburú, pẹ̀lú àpò òsùwọ̀n ẹ̀tàn?