Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Trumpet: Made of ram's horn

5 ẹsẹ · 46 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Made of ram's horn

  1. Jẹ́ kí àwọn àlùfáà méje gbé fèrè ìwo àgbò ní iwájú àpótí ẹ̀rí. Ní ọjọ́ keje, ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, pẹ̀lú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè.

  2. Nígbà tí ẹ bá gbọ́ ohùn fèrè náà, kí àwọn ènìyàn hó yèè ní igbe ńlá, nígbà náà ni odi ìlú náà yóò sì wó lulẹ̀, àwọn ènìyàn yóò sì lọ sí òkè, olúkúlùkù yóò sì wọ inú rẹ̀ lọ tààrà.”

  3. Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ọmọ Nuni pe àwọn àlùfáà ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa náà kí àwọn àlùfáà méje tí ó ru fèrè ìwo wà ní iwájú u rẹ̀.”

  4. Nígbà tí Joṣua ti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ tán, àwọn àlùfáà méje tí wọ́n gbé fèrè méje ní iwájú Olúwa kọjá sí iwájú, wọ́n sì fọn fèrè wọn, àpótí ẹ̀rí Olúwa sì tẹ̀lé wọn.

  5. Àwọn àlùfáà méje tí ó gbé ìpè ìwo àgbò méje ń lọ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, wọ́n sì ń fọ́n àwọn ìpè: àwọn tí ó hámọ́ra ogun ń lọ níwájú u wọn; àwọn ọmọ tó wà lẹ́yìn sì ń tọ àpótí ẹ̀rí Olúwa lẹ́yìn, àwọn àlùfáà sì ń fọn ìpè bí wọ́n ti ń lọ.