Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Trespass Offering: Atonement made by

7 ẹsẹ · 25 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Atonement made by

  1. àti pé gẹ́gẹ́ bí ìtánràn fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ó gbọdọ̀ mú wa fún Olúwa, abo àgùntàn tàbí abo ewúrẹ́ láti inú agbo ẹran wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀.

  2. Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wá rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà, yóò sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, a ó sì dáríjì í.

  3. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà fún èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, a ó sì dáríjì í: ìyókù sì jẹ́ ti àlùfáà, bí ẹbọ ohun jíjẹ.’ ”

  4. Kí ó ṣe àtúnṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ nínú ti àwọn ohun mímọ́, kí ó sì fi ìdámárùn-ún kún iye rẹ̀, kí ó sì kó gbogbo rẹ̀ fún àlùfáà. Àlùfáà yóò sì fi àgbò ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe ètùtù fún, a ó sì dáríjì í.

  5. kí ó mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá sọ́dọ̀ àlùfáà, fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, fún àṣìṣe tí ó ṣe láìmọ̀, a ó sì dáríjì í.

  6. Báyìí ní àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún un ètùtù ìwẹ̀nùmọ́ níwájú Olúwa, a ó sì dáríjì í nítorí ohun tó ti ṣe tó sì mú un jẹ̀bi.”

  7. Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà níwájú Olúwa fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀. A ó sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ náà jì í.