Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Titus

57 ẹsẹ · 11 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí Dema ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalonika; Kreskeni sí Galatia, Titu sí Dalimatia.

  2. Paulu, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti aposteli Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run àti ìmọ̀ òtítọ́ irú èyí tí í máa darí ènìyàn sí ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run—

  3. ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ tí ó dúró lórí ìrètí iyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run tí kì í purọ́ ti ṣe ìlérí rẹ̀ ṣáájú kí ayé tó bẹ̀rẹ̀,

  4. àti pé ní àkókò tirẹ̀, òun ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn nínú ìwàásù tí a fi lé mi lọ́wọ́ nípa àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa,

  5. Sí Titu, ọmọ mi tòótọ́ nínú ìgbàgbọ́ wa kan náà: Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Kristi Jesu Olùgbàlà wa.

  6. Ìdí tí mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Krete ni pé kí o lè ṣe àṣepé àwọn iṣẹ́ tó ṣẹ́kù. Mo sì ń rọ̀ ọ́ kí o yan àwọn alàgbà ní ìlú kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí mo ṣe darí rẹ̀.

  7. Ní kété tí mo bá ti rán Artema tàbí Tikiku sí ọ, sa gbogbo ipá rẹ láti tọ̀ mí wá ní Nikopoli, nítorí mo ti pinnu láti lo ìgbà òtútù mi níbẹ̀.