Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Throne: Of David

8 ẹsẹ · 8 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Of David

  1. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fi ìdí múlẹ̀ gidigidi.

  2. Àti nísinsin yìí, bí ó ti dájú pé Olúwa wà láààyè, ẹni tí ó ti mú mi jókòó lórí ìtẹ́ baba mi Dafidi, àti tí ó sì ti kọ́ ilé fún mi bí ó ti ṣèlérí, lónìí ni a ó pa Adonijah!”

  3. Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi, Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀, nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.

  4. Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́ àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn, àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.

  5. Ní ti gbígbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun. Yóò jẹ ọba lórí ìtẹ́ Dafidi àti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo, nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀, pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo láti ìgbà náà lọ àti títí láéláé. Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.

  6. Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò fi ìmutípara kún gbogbo olùgbé ilẹ̀ yìí pẹ̀lú ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jerusalẹmu.

  7. Nígbà náà ni ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba ẹnu ibodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé.

  8. Òun ó pọ̀, ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é, Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún.