Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Theft: Brings a curse on those who commit it
Àwọn ẹsẹ nípa Brings a curse on those who commit it
àfi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn olè jíjà àti panṣágà. Wọ́n rú gbogbo òfin, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀.
Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù. Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú omi ló ń kú.
Ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ègún tí ó jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé, nítorí gbogbo àwọn tí ó bá jalè ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀; gbogbo àwọn tí ó bá sì búra èké ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀.
Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Èmi yóò mú un jáde, Èmi yóò si wọ inú ilé olè lọ, àti inú ilé ẹni ti o bá fi orúkọ mi búra èké, yóò si wà ni àárín ilé rẹ̀, yóò si rún pẹ̀lú igi àti òkúta inú rẹ̀.’ ”
“Èmi ó sì súnmọ́ yin fún ìdájọ́. Èmi yóò sì yára ṣe ẹlẹ́rìí sí àwọn oṣó, sí àwọn panṣágà, sí àwọn abúra èké, àti àwọn tí ó fi ọ̀yà alágbàṣe pọn wọn lójú, àti àwọn tí ó ni àwọn opó àti àwọn aláìní baba lára, àti sí ẹni tí kò jẹ́ kí àjèjì rí ìdájọ́ òdodo gbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.