Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Scape Goat

10 ẹsẹ · 7 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Òun yóò sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì láti ọ̀dọ̀ gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli láti fi ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n, àti àgbò kan fún ẹbọ sísun.

  2. Lẹ́yìn náà yóò sì mú ewúrẹ́ méjì náà wá sí iwájú Olúwa ní ibi ìlẹ̀kùn àgọ́ ìpàdé.

  3. Aaroni yóò sì dìbò ní ti àwọn ewúrẹ́ méjèèjì náà, ìbò àkọ́kọ́ fún ti Olúwa, àti èkejì fún ewúrẹ́ ìpààrọ̀.

  4. Aaroni yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, yóò sì jẹ́wọ́ gbogbo ìwà búburú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ara Israẹli lé e lórí. Gbogbo ìrékọjá wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni yóò sì gbé ka orí ewúrẹ́ náà. Yóò sì rán an lọ sí ijù láti ọwọ́ ẹni tí a yàn fún iṣẹ́ náà.

  5. Ewúrẹ́ náà yóò sì ru gbogbo àìṣedéédéé wọn lọ sí ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé. Òun yóò sì jọ̀wọ́ ewúrẹ́ náà lọ́wọ́ lọ sínú ijù.

  6. Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan, yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú, yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ẹbọ sísun ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn.

  7. “Ẹni tí ó tú ewúrẹ́ ìpààrọ̀ náà sílẹ̀ yóò sì fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi, lẹ́yìn èyí ó lè wá sí ibùdó.

  8. Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀; Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀ gbogbo àìṣedéédéé wa.

  9. Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀, òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre, Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.

  10. Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára, nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ fún ikú, tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá. Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárékọjá.