Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The New Birth: Connected with adoption

4 ẹsẹ · 35 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Connected with adoption

  1. Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’ Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’ Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—

  2. ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́, tí mo dá fún ògo mi, tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”

  3. Ṣùgbọ́n iye àwọn tí ó gbà á, àní àwọn náà tí ó gbà orúkọ rẹ̀ gbọ́, àwọn ni ó fi ẹ̀tọ́ fún láti di ọmọ Ọlọ́run.

  4. Àwọn ọmọ tí kì í ṣe nípa ẹ̀jẹ̀, tàbí nípa ti ìfẹ́ ara, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípa ìfẹ́ ti ènìyàn, bí kò ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run.