Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Feast of Tabernacles: Singing hosannas
Àwọn ẹsẹ nípa Singing hosannas
Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá: ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.
Olúwa, gbà wá; Olúwa, fún wa ní àlàáfíà.
Ìbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa. Àwa ti fi ìbùkún fún ọ láti ilé Olúwa wá.
Olúwa ni Ọlọ́run, ó ti mú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn sí wa lára pẹ̀lú ẹ̀ka igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀ ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ.
Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ; ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.