Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Swine: The Gergesenes punished for having
Àwọn ẹsẹ nípa The Gergesenes punished for having
Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀ Jesu wí pé, “Bí ìwọ bá lé wa jáde, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ yìí.”
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ!” Nígbà tí wọn sì jáde, wọn lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà; sì wò ó, gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà sì rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ bèbè odò bọ́ sínú Òkun, wọ́n sì ṣègbé nínú omi.
Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá kan sì ń jẹ lẹ́bàá òkè.
Àwọn olùtọ́jú ẹran wọ̀nyí sì sálọ sí àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèké, wọ́n sì ń tan ìròyìn náà ká bí wọ́n ti ń sáré. Àwọn ènìyàn sì tú jáde láti fojú gán-án-ní ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀.