Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Stephen: Stoned

9 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Stoned

  1. Nígbà tí wọn sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọn sì payínkeke sí i.

  2. Ṣùgbọ́n Stefanu, ẹni tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó tẹjúmọ́ ọ̀run, ó sì rí ògo Ọlọ́run, àti Jesu dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.

  3. Ó sì wí pé, “Wò ó, mo rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ Ènìyàn sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”

  4. Nígbà náà ni wọn kígbe ní ohùn rara, wọn sí di etí wọ́n, gbogbo wọn sì sáré sí i, wọ́n sì rọ́ lù ú,

  5. wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sísọ ọ́ ní òkúta; àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Saulu.

  6. Bí wọ́n ti ń sọ Stefanu ní òkúta, ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Jesu Olúwa, gba ẹ̀mí mi.”

  7. Nígbà náà ni ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó kígbe sókè pé, “Olúwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn ní ọrùn.” Nígbà ti ó sì wí èyí tán, ó sùn lọ.

  8. Saulu sì wà níbẹ̀, ó sì fi àṣẹ sí ikú rẹ̀. Ní àkókò náà, inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerusalẹmu, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Judea àti Samaria, àyàfi àwọn aposteli.

  9. Nígbà tí a sì ta ẹ̀jẹ̀ Stefanu ẹlẹ́rìí rẹ sílẹ̀, èmi náà pẹ̀lú dúró níbẹ̀, mo sì ní ohùn sí ikú rẹ̀, mo sì ń ṣe ìtọ́jú aṣọ àwọn ẹni tí ó pa á.’