Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sickness: Pray for those afflicted with
Àwọn ẹsẹ nípa Pray for those afflicted with
Ó sì ṣe, baba Pubiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá.
Ẹnikẹ́ni ha ṣe àìsàn nínú yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ìjọ, kí wọ́n sì gbàdúrà sórí rẹ̀, kí wọn fi òróró kùn ún ní orúkọ Olúwa.
Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì gba aláìsàn náà là, Olúwa yóò sì gbé e dìde; bí ó bá sì ṣe pé ó ti dẹ́ṣẹ̀, a ó dáríjì í.