Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Shilonite

5 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Ó sì ṣe, ní àkókò náà Jeroboamu ń jáde kúrò ní Jerusalẹmu. Wòlíì Ahijah ti Ṣilo sì pàdé rẹ̀ lójú ọ̀nà, ó sì wọ agbádá tuntun. Àwọn méjèèjì nìkan ni ó sì ń bẹ ní oko,

  2. Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fi etí sí ti àwọn ènìyàn, nítorí tí ọ̀ràn náà ti ọwọ́ Olúwa wá láti mú ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún Jeroboamu ọmọ Nebati láti ẹnu Ahijah ará Ṣilo ṣẹ.

  3. Ó sì ṣe, bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba ó pa gbogbo ilé Jeroboamu, kò sì ku ẹnìkan tí ń mí fún Jeroboamu, ṣùgbọ́n ó run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ó sọ nípa ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ Ahijah ará Ṣilo.

  4. Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ìjọba Solomoni, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn Natani wòlíì, àti nínú ìsọtẹ́lẹ̀ Ahijah ará Ṣilo àti nínú ìran Iddo, wòlíì tí o so nípa Jeroboamu ọmọ Nebati?

  5. Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fetísí àwọn ènìyàn, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni. Láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ tí a ti sọ fún Jeroboamu ọmọ Nebati nípasẹ̀ Ahijah ará Ṣilo.