Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Shepherds: Of Christ as the good shepherd
Àwọn ẹsẹ nípa Of Christ as the good shepherd
Èmi yóò fi Olùṣọ́-àgùntàn kan ṣe olórí wọn, ìránṣẹ́ mi Dafidi, òun yóò sì tọ́jú wọn; òun yóò bọ́ wọn yóò sì jẹ́ Olùṣọ́-àgùntàn wọn.
“Dìde, ìwọ idà, sí Olùṣọ́-àgùntàn mi, àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn, àwọn àgùntàn a sì túká: èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kéékèèké.
“Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí.
Ǹjẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà, ẹni tí o tún mu olùṣọ́-àgùntàn ńlá ti àwọn àgùntàn, ti inú òkú wá, nípa ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ayérayé, àní Olúwa wa Jesu.