Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Restitution: For dishonesty

8 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ nípa For dishonesty

  1. “Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí Olúwa nípa títan ẹnìkejì rẹ̀ lórí ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ tàbí tí wọ́n fi pamọ́ sí i lọ́wọ́, tàbí bí ó bá jalè, tàbí kí ó yan ẹnìkejì rẹ̀ jẹ,

  2. tàbí kí ó rí ohun tó sọnù he tó sì parọ́ tàbí kí ó búra èké, tàbí kí ó tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ kan, irú èyí tí ènìyàn lè ṣẹ̀.

  3. Bí ó bá dẹ́ṣẹ̀ báyìí tó sì jẹ̀bi, ó gbọdọ̀ dá ohun tó jí tàbí ohun tó fi agbára gbà, tàbí ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ̀, tàbí ohun tó sọnù tó rí he,

  4. tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí. Ó gbọdọ̀ dá gbogbo rẹ̀ padà ní pípé, kí ó fi ìdámárùn-ún iye rẹ̀ kún, kí ó sì dá gbogbo rẹ̀ padà fún ẹni tí ó ni í, ní ọjọ́ tó bá ń rú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀.

  5. Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn-ún rẹ̀ lé e, kí ó sì fi fún ẹni tí òun jẹ̀bi rẹ̀.

  6. Ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì; gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì ìgbádùn nínú rẹ̀.

  7. Tí ó bá mu ògo padà, tí o sì da ohun tí o ti jí gbé padà, tí ó sì tẹ̀lé òfin tí ó ń fún ni ní ìyè, tí kò sì ṣe búburú, òun yóò yè dandan; òun kì yóò kú.

  8. Sakeu sì dìde, ó sì wí fún Olúwa pé, “Wò ó, Olúwa, ààbọ̀ ohun ìní mi ni mo fi fún tálákà; bí mo bá sì fi èké gba ohun kan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, èmi san án padà ní ìlọ́po mẹ́rin!”