Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Race: 2. Foot race, figurative

7 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ nípa 2. Foot race, figurative

  1. Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá, òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje.

  2. Mo ti rí ohun mìíràn lábẹ́ oòrùn. Eré ìje kì í ṣe fún ẹni tí ó yára tàbí ogun fún alágbára, bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kò wà fún ọlọ́gbọ́n tàbí ọrọ̀ fún ẹni tí ó ní òye tàbí ojúrere fún ẹni tí ó ní ìmọ̀; ṣùgbọ́n ìgbà àti èsì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.

  3. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó ní ipa nínú eré ìje ni ó máa ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnìkan ṣoṣo ni ń gba ipò ẹ̀bùn tí ó ga jù. Nítorí náà, ẹ sá eré ìje yín kí ẹ ba à le borí.

  4. Ẹ̀yin ti ń sáré dáradára. Ta ni dí yin lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ràn sí òtítọ́?

  5. Bí ẹ sì ṣe di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kristi pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán.

  6. Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa,

  7. kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.