Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Private Prayer: Christ was constant in

6 ẹsẹ · 28 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Christ was constant in

  1. Lẹ́yìn tí ó tú ìjọ ènìyàn ká tán, ó gun orí òkè lọ fúnra rẹ̀ láti lọ gba àdúrà. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, òun wà nìkan níbẹ̀,

  2. Nígbà náà ni Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibi kan ti à ń pè ní ọgbà Getsemane, ó wí fún wọn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbàdúrà lọ́hùn ún ni.”

  3. Òun lọ sí iwájú díẹ̀ sí i, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé, “Baba mi, bí ó bá ṣe é ṣe, jẹ́ kí a mú ago yìí ré mi lórí kọjá, ṣùgbọ́n ìfẹ́ tìrẹ ni mo fẹ́ kí ó ṣẹ, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.”

  4. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu nìkan jáde lọ sí aginjù kan, láti lọ gbàdúrà.

  5. Ó sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀: ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?”

  6. Bí ó sì ti ń gbàdúrà, àwọ̀ ojú rẹ̀ yípadà, aṣọ rẹ̀ sì funfun gbòò,