Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pathros: Jewish captives in

4 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Jewish captives in

  1. Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun.

  2. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá nípa àwọn Júù tí ń gbé ní ìsàlẹ̀ Ejibiti ní Migdoli, Tafanesi àti Memfisi àti ní apá òkè Ejibiti:

  3. Lẹ́yìn èyí, gbogbo àwọn ọkùnrin tí ẹ bá mọ̀ pé, ìyàwó wọn sun tùràrí sí àwọn òrìṣà pẹ̀lú àwọn obìnrin tí ó bá wá àwọn ènìyàn púpọ̀, pàápàá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní òkè àti ìsàlẹ̀ Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni a wí fún Jeremiah.

  4. Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Ejibiti padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Paturosi, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀.