Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Paralysis

8 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Siria ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú ààrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn.

  2. O sì wí pé, “Olúwa, ọmọ ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ ààrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá.”

  3. Nítorí náà Jesu sì wí fún balógun ọ̀run náà pé, “Máa lọ ilé, ohun tí ìwọ gbàgbọ́ ti rí bẹ́ẹ̀.” A sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ náà láradá ní wákàtí kan náà.

  4. àwọn ọkùnrin kan gbé arọ kan tọ̀ ọ́ wá lórí àkéte rẹ̀. Nígbà tí Jesu rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ tújúká, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

  5. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì ni.” Ó sì wí fún arọ náà pé, “Dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ ilé rẹ.”

  6. Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúnkùn ún ni ó sì gba ìmúláradá.

  7. Níbẹ̀ ni ó rí ọkùnrin kan ti a pè ní Aenea tí ó ti dùbúlẹ̀ lórí àkéte ni ọdún mẹ́jọ, ó ní ààrùn ẹ̀gbà.

  8. Peteru sì wí fún un pé, “Aenea, Jesu Kristi mú ọ láradá; dìde kí ó sì tún àkéte rẹ ṣe.” Ó sì dìde lójúkan náà.