Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pantomime

12 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. ní àkókò náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa ti ẹnu Isaiah ọmọ Amosi jáde. Ó sọ fún un pé, “Mú aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò ní ara rẹ kí o sì bọ́ sálúbàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà.

  2. Lẹ́yìn náà ni Olúwa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ mi Isaiah ti lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí àmì àti àpẹẹrẹ sí Ejibiti àti Kuṣi,

  3. “Nísinsin yìí, ìwọ ọmọ ènìyàn, mú amọ̀ ṣíṣù kan, gbé e sí iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán ìlú Jerusalẹmu sí orí rẹ̀.

  4. Kí o sì dó tì í, kí o sì mọ ilé ìṣọ́ tì í, kí o sì mọ odi tì í, kí o sì gbé ogun sí i, kí o sì to òòlù yí i ká.

  5. Kí o sì fi àwo irin kan ṣe ògiri láàrín rẹ̀ àti ìlú yìí, kí o sì kọjú sí i, a ó sì dó tì í, ìwọ yóò sì dó tì í. Èyí yóò jẹ́ àmì fún ilé Israẹli.

  6. “Lẹ́yìn èyí, lọ fi ẹ̀gbẹ́ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli lé orí ara rẹ. Iye ọjọ́ tí ìwọ bá fi sùn náà ni ìwọ yóò fi ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  7. Nítorí mo fi iye ọdún tí wọ́n fi ṣẹ̀ fún ọ gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ tí ìwọ yóò lò. Nítorí náà, ìwọ yóò ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390).

  8. “Tí o bá parí èyí, tún fi ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún dùbúlẹ̀ kí o sì ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda fún ogójì ọjọ́, nítorí pé ọjọ́ kan ló dúró fún ọdún kan.

  9. Ìwọ dojúkọ ìgbógunti Jerusalẹmu, na ọwọ́ rẹ sí i, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlú náà.

  10. Èmi yóò dè ọ́ ní okùn dé bi pé ìwọ kò ní í le yírapadà láti ìhà ọ̀tún sí ìhà òsì títí tí ọjọ́ ìgbóguntì rẹ yóò fi pé.

  11. “Ọmọ ènìyàn, jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ìwárìrì, sì mu omi rẹ pẹ̀lú ìwárìrì àti àìbalẹ̀ àyà.

  12. Nígbà tí ó sì dé ọ̀dọ̀ wa, ó mú àmùrè Paulu, ó sì de ara rẹ̀ ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Ẹ̀mí Mímọ́ wí, ‘Báyìí ni àwọn Júù tí ó wà ní Jerusalẹmu yóò de ọkùnrin tí ó ní àmùrè yìí, wọn ó sì fi í lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́.’ ”