Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Palm Tree: Wood of, used in the temple
Àwọn ẹsẹ nípa Wood of, used in the temple
Lára àwọn ògiri tí ó yí ilé náà ká, nínú àti lóde, ó sì ya àwòrán àwọn kérúbù sí i àti ti igi ọ̀pẹ, àti ti ìtànná ewéko.
Àti lára ìlẹ̀kùn igi olifi náà ni ó ya àwòrán àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí, ó sì fi wúrà bò wọ́n, ó sì tan wúrà sí ara àwọn kérúbù àti sí ara igi ọ̀pẹ.
Ó sì ya àwòrán kérúbù, àti ti igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí ara wọn, ó sì fi wúrà bò ó, èyí tí ó tẹ́ sórí ibi tí ó gbẹ́.
Ó fi igi firi bo ilé yàrá ńlá náà ó sì bò ó pẹ̀lú kìkì wúrà, ó sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú igi ọ̀pẹ àti àwòrán ẹ̀wọ̀n.