Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ostriches: General references

10 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

  1. “Ìwọ ni yóò ha fi ìyẹ́ dáradára fún ọ̀kín bí, tàbí ìyẹ́ àti ìhùhù bo ògòǹgò?

  2. Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀, a sì mú wọn gbóná nínú ekuru;

  3. tí ó sì gbàgbé pé, ẹsẹ̀ lè tẹ̀ wọ́n fọ́, tàbí pé ẹranko igbó lè tẹ̀ wọ́n fọ́.

  4. Kò ní àánú sí àwọn ọmọ rẹ̀ bí ẹni pé wọn kì í ṣe tirẹ̀; asán ni iṣẹ́ rẹ̀ láìní ìbẹ̀rù;

  5. nítorí pé Ọlọ́run kò fún un ní ọgbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un.

  6. Nígbà tí ó gbé ara sókè, ó gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin.

  7. Ṣùgbọ́n àwọn ẹranko igbó ni yóò dùbúlẹ̀ níbẹ̀, àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn, níbẹ̀ ni àwọn òwìwí yóò máa gbé níbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́ igbó yóò ti máa bẹ́ kiri.

  8. Ẹ̀gún yóò sì hù jáde nínú àwọn ààfin rẹ̀ wọ̀nyí, ẹ̀gún ọ̀gán nínú ìlú olódi rẹ̀. Yóò jẹ́ ibùgbé àwọn akátá àti àgbàlá fún àwọn òwìwí.

  9. Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi, àwọn ajáko àti àwọn òwìwí, nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ sísá, láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,

  10. Àwọn ajáko pèsè ọmú wọn fún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kàn bí ògòǹgò ní aginjù.