Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Meat Offerings: Laid up in a chamber of the temple

3 ẹsẹ · 28 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Laid up in a chamber of the temple

  1. Àwọn ènìyàn Israẹli, àti àwọn ọmọ Lefi gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró wá sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa ń dúró sí. “Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”

  2. Ó sì ti pèsè yàrá ńlá kan fún un, èyí tí a ń lò tẹ́lẹ̀ fún ìtọ́jú ọrẹ ọkà, tùràrí àti àwọn ohun èlò tẹmpili àti ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró ti a fi lélẹ̀ bí ìlànà fún àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà àti pẹ̀lú gbogbo ọrẹ fún àwọn àlùfáà.

  3. Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn yàrá àríwá àti àwọn yàrá gúúsù, tí ó wà níwájú ibi tí a yà sọ́tọ̀ àwọn ni yàrá mímọ́, níbi tí àwọn àlùfáà ti ń súnmọ́ Olúwa yó máa jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ; níbẹ̀ ní wọn o máa gbé ohun mímọ́ jùlọ kà, àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; nítorí ibẹ̀ jẹ́ mímọ́.