Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Maachah: 4. Called Michaiah, mother of Abijam and grandmother of Asa
Àwọn ẹsẹ nípa 4. Called Michaiah, mother of Abijam and grandmother of Asa
Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu ní ọdún mọ́kànlélógójì. Orúkọ ìyá ńlá rẹ̀ sì ni Maaka, ọmọbìnrin Absalomu.
Asa sì ṣe èyí tí ó dára lójú Olúwa, bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe.
Ó sì mú àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà kúrò ní ilẹ̀ náà, ó sì kó gbogbo ère tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe kúrò.
Ó sì mú Maaka ìyá ńlá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún Aṣerah òrìṣà rẹ̀. Asa sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì jó o ní àfonífojì Kidironi.
Nígbà náà, ó fẹ́ Maaka ọmọbìnrin Absalomu, tí ó bí Abijah fún Attai, Sisa àti Ṣelomiti.
Rehoboamu fẹ́ràn Maaka ọmọbìnrin Absalomu ju èyíkéyìí nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀ lọ. Ní gbogbo rẹ̀, ó ní ìyàwó méjìdínlógún àti ọgọ́ta àlè ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́ta ọmọbìnrin.
Rehoboamu yan Abijah ọmọ Maaka láti jẹ́ olóyè ọmọ-aládé láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀, kí ó ba à lè ṣe é ní ọba.
Ó hùwà ọlọ́gbọ́n, nípa fí fọ́n díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ jákèjádò ká àwọn agbègbè Juda àti Benjamini àti sí gbogbo àwọn ìlú ńlá olódi. Ó fún wọn ní ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n fẹ́, ó sì fẹ́ ọ̀pọ̀ ìyàwó fún wọn.