Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Joy

75 ẹsẹ · 91 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi, ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.

  2. Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára; nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.

  3. Mo ti gbé Olúwa síwájú mi ní ìgbà gbogbo. Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

  4. Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀; ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,

  5. Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi; ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,

  6. nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́. Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.

  7. Ti Dafidi. Maskili. Ìbùkún ni fún àwọn tí a dárí ìrékọjá wọn jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.

  8. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

  9. A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ; pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.

  10. Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi; èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.

  11. Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi, mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.

  12. Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì, Olúwa wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.

  13. Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́, wọn ń yin òdodo rẹ.

  14. Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn.

  15. Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo, kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.

  16. Saamu. Fún ọpẹ́. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé.

  17. Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa, ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn

  18. Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀, ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa.

  19. Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́ tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

  20. Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn yóò fi ayọ̀ ka.

  21. Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ, tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́, lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá, yóò sì ru ìtí rẹ̀.

  22. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdún tí ó le è lò láyé ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùn nítorí wọn ó pọ̀. Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni.

  23. Jẹ́ kí inú rẹ dùn, ìwọ ọ̀dọ́mọdé ní ìgbà tí o wà ní èwe kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ fún ọ ní ayọ̀ ní ìgbà èwe rẹ. Tẹ̀lé ọ̀nà ọkàn rẹ àti ohunkóhun tí ojú rẹ rí ṣùgbọ́n mọ̀ dájú pé nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́.

  24. Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé, “Èmi ó yìn ọ́, Olúwa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀ ìwọ sì ti tù mí nínú.

  25. Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi, èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù. Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi, òun ti di ìgbàlà mi.”