Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Harlot: Shamelessness of

23 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Shamelessness of

  1. (Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí, ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;

  2. bí ó ti ń já níhìn-ín ní ó ń já lọ́hùn ún gbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.)

  3. Ó dìímú, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu pẹ̀lú ojú díndín ó wí pé,

  4. “Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé; lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.

  5. Nítorí náà ni n o ṣe jáde wá pàdé è rẹ; mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!

  6. Mo ti tẹ́ ibùsùn mi pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Ejibiti.

  7. Mo ti fi nǹkan olóòórùn dídùn sí ibùsùn mi bí i òjìá, aloe àti kinamoni.

  8. Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀; jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!

  9. Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé; ó ti lọ sí ìrìnàjò jíjìn.

  10. Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́ kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”

  11. Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà; ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.

  12. Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà, bí i màlúù tí ń lọ sí ibi pípa, tàbí bí àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi okùn ìso.

  13. Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀, bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn, láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.

  14. Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi fọkàn sí nǹkan tí mo sọ.

  15. Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀, tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.

  16. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀. Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.

  17. Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààrà sí isà òkú, tí ó lọ tààrà sí àgbàlá ikú.

  18. Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo; ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìní ìmọ̀.

  19. Ó jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀ lórí ìjókòó níbi tí ó ga jù láàrín ìlú,

  20. ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ, tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.

  21. “Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!” Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.

  22. “Omi tí a jí mu dùn oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”

  23. Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀, pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú.