Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Gentiles: Depraved and wicked

5 ẹsẹ · 40 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Depraved and wicked

  1. Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe.

  2. Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àrankàn; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà búburú; wọ́n jẹ́ afọ̀rọ̀kẹ́lẹ́ ba ni jẹ́.

  3. Asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, akórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọràn sí òbí,

  4. aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgbọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú.

  5. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n.