Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Forgetting God

14 ẹsẹ · 19 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Kí ó má ba à jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀,

  2. nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i,

  3. nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbéga, tí ẹ̀yin yóò sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá, nínú oko ẹrú.

  4. Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀, ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀.

  5. Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.

  6. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa, síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀.

  7. Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.

  8. Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá, ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú, tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

  9. Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.

  10. Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ; tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀.

  11. Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àṣàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hù jáde, àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n ẹ mú kí wọ́n rúdí, síbẹ̀síbẹ̀ ìkórè kò ní mú nǹkan wá ní ọjọ́ ààrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.

  12. tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ, ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́ nítorí ìbínú àwọn aninilára, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ìpanirun? Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà?

  13. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọ wọn kò ní kú sínú túbú wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà.

  14. Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ń ru Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.