Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Flattery: Absalom

5 ẹsẹ · 20 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Absalom

  1. Absalomu sì dìde ní kùtùkùtù, ó sì dúró ní apá kan ọ̀nà ẹnu ibodè. Bí ẹnìkan bá ní ẹjọ́ tí ó ń fẹ́ mú tọ ọba wá fún ìdájọ́, a sì pè é sọ́dọ̀ rẹ̀, a sì bi í pé, “Ará ìlú wo ni ìwọ?” Òun a sì dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ti inú ọ̀kan nínú ẹ̀yà Israẹli wá.”

  2. Absalomu yóò sì wí fún un pé, “Wò ó, ọ̀ràn rẹ ṣá dára, ó sì tọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ọba fi àṣẹ fún láti gbọ́ ọ̀ràn rẹ.”

  3. Absalomu a sì wí pé, “À bá jẹ́ fi mi ṣe onídàájọ́ ní ilẹ̀ yìí! Kí olúkúlùkù ẹni tí ó ní ẹjọ́ tàbí ọ̀ràn kan bá à lè máa tọ̀ mí wá, èmi ìbá sì ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún un.”

  4. Bẹ́ẹ̀ ni bí ẹnìkan bá sì súnmọ́ láti tẹríba fún un, òun a sì nawọ́ rẹ̀, a sì dìímú, a sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.

  5. Irú ìwà báyìí ni Absalomu a máa hù sí gbogbo Israẹli tí ó tọ́ ọba wá nítorí ìdájọ́, Absalomu sì fi fa ọkàn àwọn ènìyàn Israẹli sọ́dọ̀ rẹ̀.