Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Fishes
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
“ ‘Nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá tí ń gbé inú omi Òkun, àti nínú odò: èyíkéyìí tí ó bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ́.
Ṣùgbọ́n nínú gbogbo ẹ̀dá tí ń gbé inú òkun àti nínú odò tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́, yálà nínú gbogbo àwọn tí ń rákò tàbí láàrín gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè yòókù tí ń gbé inú omi àwọn ni kí ẹ kórìíra.
Nígbà tí ẹ ti kórìíra wọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn: ẹ gbọdọ̀ kórìíra òkú wọn.
Ohunkóhun tí ń gbé inú omi tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́ gbọdọ̀ jásí ìríra fún yín.
Wọ́n sì dalóhùn pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì lọ níhìn-ín.”
Ó wí pé, “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí.”
Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn.
Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá.
Iye àwọn ènìyàn ni ọjọ́ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin, láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.
Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ó wí fún Simoni pé, “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.”
Simoni sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan kan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.”
Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja: àwọ̀n wọn sì ya.
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ sọ àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ̀yin yóò sì rí.” Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọn kò sì lè fà á jáde nítorí ọ̀pọ̀ ẹja.
Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà tí Jesu fẹ́ràn wí fún Peteru pé, “Olúwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Olúwa ni, bẹ́ẹ̀ ni ó di àmùrè ẹ̀wù rẹ̀ mọ́ra, nítorí tí ó wà ní ìhòhò, ó sì gbé ara rẹ̀ sọ sínú Òkun.
Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù mú ọkọ̀ ojú omi kékeré kan wá nítorí tí wọn kò jìnà sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ìwọ̀n igba ìgbọ̀nwọ́; wọ́n ń wọ́ àwọ̀n náà tí ó kún fún ẹja.