Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Fishermen: Certain apostles
Àwọn ẹsẹ nípa Certain apostles
Bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Simoni, ti à ń pè ní Peteru, àti Anderu arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń sọ àwọ̀n wọn sínú Òkun nítorí apẹja ni wọ́n.
Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”
Lójúkan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sebede baba wọn, wọ́n ń di àwọ̀n wọn, Jesu sì pè àwọn náà pẹ̀lú.
Simoni Peteru, àti Tomasi tí a ń pè ní Didimu, àti Natanaeli ará Kana ti Galili, àti àwọn ọmọ Sebede, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjì mìíràn jùmọ̀ wà pọ̀.
Simoni Peteru wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ pẹja!” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi; ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun.