Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Famine: Sent as a judgment

56 ẹsẹ · 51 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Sent as a judgment

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi yóò fọ́ agbára ìgbéraga yín, ojú ọ̀run yóò le koko bí irin, ilẹ̀ yóò sì le bí idẹ (òjò kò ní rọ̀: ilẹ̀ yín yóò sì le).

  2. Ẹ ó máa lo agbára yín lásán torí pé ilẹ̀ yín kì yóò so èso, bẹ́ẹ̀ ni àwọn igi yín kì yóò so èso pẹ̀lú.

  3. “ ‘Bí ẹ bá tẹ̀síwájú láì gbọ́ tèmi, Èmi yóò tún fa ìjayà yín le ní ìgbà méje gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín.

  4. Èmi yóò rán àwọn ẹranko búburú sí àárín yín, wọn yóò sì pa àwọn ọmọ yín, wọn yóò run agbo ẹran yín, díẹ̀ nínú yín ni wọn yóò ṣẹ́kù kí àwọn ọ̀nà yín lè di ahoro.

  5. “ ‘Bí ẹ kò bá tún yípadà lẹ́yìn gbogbo ìjìyà wọ̀nyí, tí ẹ sì tẹ̀síwájú láti lòdì sí mi.

  6. Èmi náà yóò lòdì sí yín. Èmi yóò tún fa ìjìyà yín le ní ìlọ́po méje ju ti ìṣáájú.

  7. Èmi yóò mú idà wá bá yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín láti fi gbẹ̀san májẹ̀mú mi tí ẹ kò pamọ́. Bí ẹ ba sálọ sí ìlú yín fún ààbò, Èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín yín, àwọn ọ̀tá yín, yóò sì ṣẹ́gun yín.

  8. Èmi yóò dá ìpèsè oúnjẹ yín dúró, dé bi pé: inú ààrò kan ni obìnrin mẹ́wàá yóò ti máa se oúnjẹ yín. Òsùwọ̀n ni wọn yóò fi máa yọ oúnjẹ yín, ẹ ó jẹ ṣùgbọ́n, ẹ kò ní yó.

  9. “ ‘Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ kò bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì lòdì sí mi,

  10. ní ìbínú mi, èmi yóò korò sí yín, èmi tìkára mi yóò fìyà jẹ yín ní ìgbà méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.

  11. Ebi náà yóò pa yín dé bi pé ẹ ó máa jẹ ẹran-ara àwọn ọmọ yín ọkùnrin, àti àwọn ọmọ yín obìnrin.

  12. Ojú ọ̀run tí ó wà lórí rẹ yóò jẹ́ idẹ, ilẹ̀ tí ń bẹ níṣàlẹ̀ rẹ yóò sì jẹ́ irin.

  13. Olúwa yóò yí òjò ilẹ̀ rẹ sí eruku àti ẹ̀tù; láti ọ̀run ni yóò ti máa sọ̀kalẹ̀ sí ọ, títí tí ìwọ yóò fi run.

  14. Ìwọ yóò gbin irúgbìn púpọ̀ ṣùgbọ́n ìwọ yóò kórè kékeré, nítorí eṣú yóò jẹ ẹ́ run.

  15. Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà púpọ̀ ìwọ yóò sì ro wọ́n ṣùgbọ́n kò ní mú wáìnì náà tàbí kó àwọn èso jọ, nítorí kòkòrò yóò jẹ wọ́n run.

  16. Ìwọ yóò ní igi olifi jákèjádò ilẹ̀ rẹ ṣùgbọ́n ìwọ kò ní lo òróró náà, nítorí olifi náà yóò rẹ̀ dànù.

  17. Ìwọ yóò ní àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ṣùgbọ́n ìwọ kò nípa wọ́n mọ́, nítorí wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.

  18. Ọ̀wọ́ eṣú yóò gba gbogbo àwọn igi rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ.

  19. Ó sọ odò di aginjù, àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.

  20. Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀ nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀.

  21. Kíyèsi i, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, fẹ́ mú ìpèsè àti ìrànlọ́wọ́ kúrò ní Jerusalẹmu àti Juda gbogbo ìpèsè oúnjẹ àti ìpèsè omi.

  22. Àwọn akíkanjú àti jagunjagun, adájọ́ àti wòlíì, aláfọ̀ṣẹ àti alàgbà,

  23. balógun àádọ́ta àti àwọn ènìyàn, onípò gíga; olùdámọ̀ràn, oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́ àti ògbójú oníṣègùn.

  24. “Èmi ó sọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin di aláṣẹ wọn, ọ̀dọ́mọdé lásán làsàn ni yóò sì máa jẹ ọba lórí i wọn.”

  25. Àwọn ènìyàn yóò sì máa pọ́n ọmọnìkejì, wọn lójú ẹnìkan sí ẹnìkejì rẹ̀, aládùúgbò sí aládùúgbò rẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ yóò gbógun ti àwọn àgbàgbà, àwọn mẹ̀kúnnù yóò dìde sí ọlọ́lá.