Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Famine: Grief and mourning

3 ẹsẹ · 51 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Grief and mourning

  1. Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀; ẹ pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà, nítorí alikama àti nítorí ọkà barle; nítorí ìkórè oko ṣègbé.

  2. Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù; igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú, àti igi apiili, gbogbo igi igbó ni o rọ. Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

  3. Ẹ di ara yín ni àmùrè, sí pohùnréré ẹkún ẹ̀yin àlùfáà: ẹ pohùnréré ẹkún, ẹ̀yin ìránṣẹ́ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi, nítorí tí a dá ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu dúró ní ilé Ọlọ́run yín.