Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Eternal Life

19 ẹsẹ · 33 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, kí ènìyàn lè máa jẹ nínú rẹ̀ kí ó má sì kú.

  2. Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé, oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.”

  3. Nítorí náà ni àwọn Júù ṣe ń bá ara wọn jiyàn, pé, “Ọkùnrin yìí yóò ti ṣe lè fi ara rẹ̀ fún wa láti jẹ?”

  4. Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá jẹ ara Ọmọ Ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀yin kò ní ìyè nínú yin.

  5. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun. Èmi o sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.

  6. Nítorí ara mi ni ohun jíjẹ nítòótọ́, àti ẹ̀jẹ̀ mi ni ohun mímu nítòótọ́.

  7. Ẹni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ń gbé inú mi, èmi sì ń gbé inú rẹ̀.

  8. Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, tí èmi sì yè nípa Baba gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó jẹ mí, òun pẹ̀lú yóò yè nípa mi.

  9. Èyí sì ni oúnjẹ náà tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe bí àwọn baba yín ti jẹ manna, tí wọ́n sì kú, ẹni tí ó bá jẹ́ oúnjẹ yìí yóò yè láéláé.”

  10. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan,

  11. kò sí ẹni tí òye yé, kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.

  12. Gbogbo wọn ni ó ti yapa, wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè; kò sí ẹni tí ń ṣe rere, kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”

  13. “Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀fun wọn: ahọ́n wọn n sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.” “Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”

  14. “Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”

  15. “Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀,

  16. ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn.

  17. Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀,”

  18. “Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”

  19. Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.