Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Eternal Life: Cannot be inherited by works

10 ẹsẹ · 33 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Cannot be inherited by works

  1. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan,

  2. kò sí ẹni tí òye yé, kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.

  3. Gbogbo wọn ni ó ti yapa, wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè; kò sí ẹni tí ń ṣe rere, kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”

  4. “Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀fun wọn: ahọ́n wọn n sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.” “Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”

  5. “Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”

  6. “Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀,

  7. ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn.

  8. Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀,”

  9. “Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”

  10. Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.