Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Drought

8 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Ojú ọ̀run tí ó wà lórí rẹ yóò jẹ́ idẹ, ilẹ̀ tí ń bẹ níṣàlẹ̀ rẹ yóò sì jẹ́ irin.

  2. Olúwa yóò yí òjò ilẹ̀ rẹ sí eruku àti ẹ̀tù; láti ọ̀run ni yóò ti máa sọ̀kalẹ̀ sí ọ, títí tí ìwọ yóò fi run.

  3. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn:

  4. “Juda káàánú, àwọn ìlú rẹ̀ kérora wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn, igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu.

  5. Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi, wọ́n lọ sí ìdí àmù ṣùgbọ́n wọn kò rí omi. Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo; ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn, wọ́n sì bo orí wọn.

  6. Ilẹ̀ náà sán nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà; ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo, wọ́n sì bo orí wọn.

  7. Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀, torí pé kò sí koríko.

  8. Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò ojú wọn kò ríran nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.”