Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Disobedience to God: The prophet
Àwọn ẹsẹ nípa The prophet
Bí wọ́n sì ti jókòó ti tábìlì, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ wòlíì tí ó mú un padà wá pé;
Ó sì kígbe sí ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti Juda wá wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ ti ba ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ́, ìwọ kò sì pa àṣẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́.
Ìwọ padà, ìwọ sì ti jẹ oúnjẹ, ìwọ sì ti mu omi níbi tí ó ti sọ fún ọ pé kí ìwọ kí ó má ṣe jẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Nítorí náà, a kì yóò sin òkú rẹ sínú ibojì àwọn baba rẹ.’ ”
Nígbà tí ènìyàn Ọlọ́run sì ti jẹun tán àti mu omi tan, wòlíì tí ó ti mú u padà sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún un.