Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Christian Liberty

16 ẹsẹ · 29 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Ẹ ya àádọ́ta ọdún náà sọ́tọ̀ kí ẹ sì kéde òmìnira fún gbogbo ẹni tí ń gbé ilẹ̀ náà. Yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Kí olúkúlùkù padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀.

  2. Àádọ́ta ọdún ni yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Ẹ má ṣe gbin ohunkóhun, ẹ kò sì gbọdọ̀ kórè ohun tí ó hù fúnra rẹ̀ tàbí kí ẹ kórè ọgbà àjàrà tí ẹ kò dá.

  3. Torí pé ọdún ìdásílẹ̀ ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún yín. Ẹ jẹ ohun tí ẹ mú jáde nínú oko náà.

  4. “ ‘Ní ọdún ìdásílẹ̀ yìí, kí olúkúlùkù gbà ohun ìní rẹ̀ padà.

  5. “ ‘Bí ẹ bá ta ilẹ̀ fún ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín tàbí bí ẹ bá ra èyíkéyìí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ.

  6. Kí ẹ ra ilẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn yín ní gẹ́gẹ́ bí iye owó tí ó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ pé, kí òun náà sì ta ilẹ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí iye ọdún rẹ̀ tókù láti kórè.

  7. Bí iye ọdún rẹ̀ bá gùn, kí iye owó rẹ̀ pọ̀, bí iye ọdún rẹ̀ bá kúrú, kí iye owó rẹ̀ kéré, torí pé ohun tí ó tà gan an ní iye èso rẹ̀.

  8. Ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ, ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

  9. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwa, nígbà tí àwa wà ní èwe, àwa wà nínú ìdè lábẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.

  10. Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ jáde wá, ẹni tí a bí nínú obìnrin tí a bí lábẹ́ òfin.

  11. Láti ra àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin padà, kí àwa lè gba ìsọdọmọ.

  12. Nítorí a ti kọ ọ́ pé, Abrahamu ní ọmọ ọkùnrin méjì, ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ẹrúbìnrin, àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin.

  13. Ṣùgbọ́n a bí èyí tí ṣe ti ẹrúbìnrin nípa ti ara, ṣùgbọ́n èyí ti òmìnira obìnrin ni a bí nípa ìlérí.

  14. Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ: nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ní májẹ̀mú méjèèjì; ọ̀kan láti orí òkè Sinai wá, tí a bí lóko ẹrú, tí í ṣe Hagari.

  15. Nítorí Hagari yìí ni òkè Sinai Arabia, tí ó sì dúró fún Jerusalẹmu tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀.

  16. Ṣùgbọ́n Jerusalẹmu ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa.