Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Boil

10 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Yóò sì di eruku lẹ́búlẹ́bú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, yóò sì di oówo ti ń tú pẹ̀lú ìléròrò sí ara àwọn ènìyàn àti ẹran jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.”

  2. Nígbà náà ni wọ́n bú eérú gbígbóná láti inú ààrò, wọ́n dúró ní iwájú Farao. Mose sì ku eérú náà sínú afẹ́fẹ́, ó sì di oówo tí ń tú pẹ̀lú ìléròrò ni ara àwọn ènìyàn àti lára ẹran.

  3. “Bí oówo bá mú ẹnikẹ́ni nínú ara rẹ̀ tí ó sì san.

  4. Tí ìwú funfun tàbí àmì funfun tí ó pọ́n díẹ̀ bá farahàn ní ojú ibi tí oówo náà wà: kí ẹni náà lọ sọ fún àlùfáà.

  5. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ó bá jinlẹ̀ ju awọ ara rẹ̀ lọ tí irun tirẹ̀ sì ti di funfun, kí àlùfáà pe ẹni náà ni aláìmọ́. Ààrùn ara tí ó le ràn ló yọ padà lójú oówo náà.

  6. Bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí kò sì sí irun funfun níbẹ̀ tí ó sì ti gbẹ, kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.

  7. Bí ó bá ràn ká awọ ara, kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́. Ààrùn tí ó ń ràn ni èyí.

  8. Ṣùgbọ́n bí ojú ibẹ̀ kò bá yàtọ̀, tí kò sì ràn kára, èyí jẹ́ àpá oówo lásán, kí àlùfáà pe ẹni náà ni mímọ́.

  9. Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ Jobu ní oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀.

  10. Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń họ ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú.