Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Blasphemy: General references

81 ẹsẹ · 19 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọmọkùnrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli baba rẹ̀ sì jẹ́ ará Ejibiti. Ó jáde lọ láàrín àwọn ọmọ Israẹli, ìjà sì ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ láàrín òun àti ọmọ Israẹli kan.

  2. Ọmọkùnrin arábìnrin Israẹli náà sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa pẹ̀lú èpè, wọ́n sì mú un tọ Mose wá. (Orúkọ ìyá rẹ̀ ní Ṣelomiti, ọmọbìnrin Debiri, ti ẹ̀yà Dani.)

  3. Wọ́n fi í sínú túbú kí Olúwa to sọ ohun tí wọn yóò ṣe fún wọn.

  4. Olúwa sì sọ fún Mose pé,

  5. “Mú asọ̀rọ̀-òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fihàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa.

  6. Sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣépè lé Ọlọ́run rẹ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

  7. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa ni kí ẹ pa, kí gbogbo àpéjọpọ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa, yálà àlejò ni tàbí ọmọ bíbí Israẹli, bí ó bá ti sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa, pípa ni kí ẹ pa á.

  8. Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn, èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi.

  9. Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá, ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí.

  10. Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi, ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi.

  11. Kí ẹnìkan sá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi, kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì ṣe dáyà fò mí.

  12. Nígbà náà ni èmi ìbá sọ̀rọ̀, èmi kì bá sì bẹ̀rù rẹ̀; ṣùgbọ́n bí ó tí dúró tì mí, kò ri bẹ́ẹ̀ fún mi.

  13. Èmi yóò wí fún Ọlọ́run pé, má ṣe dá mi lẹ́bi; fihàn mí nítorí ìdí ohun tí ìwọ fi ń bá mi jà.

  14. Ó ha tọ́ tí ìwọ ìbá fi máa ni mí lára, tí ìwọ ìbá fi máa gan iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, tí ìwọ yóò fi máa tàn ìmọ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn búburú?

  15. Ojú rẹ kì ha ṣe ojú ènìyàn bí? Tàbí ìwọ a máa ríran bí ènìyàn ti í ríran?

  16. Ọjọ́ rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn, ọdún rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn,

  17. tí ìwọ fi ń béèrè àìṣedéédéé mi, tí ìwọ sì fi wá ẹ̀ṣẹ̀ mi rí?

  18. Ìwọ mọ̀ pé èmi kì í ṣe oníwà búburú, kò sì sí ẹni tí ó le gbà mí kúrò ní ọwọ́ rẹ?

  19. Ẹ̀yin fẹ́ sọ ìsọkúsọ fún Ọlọ́run? Ki ẹ sì fi ẹ̀tàn sọ̀rọ̀ gbè é?

  20. Ẹ̀yin fẹ́ ṣe ojúsàájú rẹ̀? Ẹ̀yin fẹ́ gbèjà fún Ọlọ́run?

  21. Ó ha dára to tí yóò hú àṣírí yín síta, tàbí kí ẹ̀yin tàn án bí ẹnìkan ti í tan ẹnìkejì?

  22. Ìwọ ó fa ewé ti afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síyìn-ín sọ́hùn-ún ya bi? Ìwọ a sì máa lépa ìyàngbò?

  23. Nítorí pé ìwọ kọ̀wé ohun kíkorò sí mi, o sì mú mi jogún àìṣedéédéé èwe mi.

  24. Ìwọ kàn àbà mọ́ mi lẹ́sẹ̀ pẹ̀lú, ìwọ sì ń wò ipa ọ̀nà ìrìn mi ní àwòfín; nípa fífi ìlà yí gígísẹ̀ mi ká.

  25. Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdì sí Ọlọ́run, ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmarè,