Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Amalekites

13 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Olúwa sì sọ fun Mose pé. “Kọ èyí sì inú ìwé fún ìrántí, kí o sì sọ fún Joṣua pẹ̀lú; nítorí èmi yóò pa ìrántí Amaleki run pátápátá kúrò lábẹ́ ọ̀run.”

  2. Ó wí pé, “A gbé ọwọ́ sókè sí ìtẹ́ Olúwa. Olúwa yóò bá Amaleki jagun láti ìran dé ìran.”

  3. Àwọn Amaleki ń gbé ní ìhà gúúsù; àwọn ará Hiti, àwọn ará Jebusi àti àwọn ará Amori ni wọ́n ń gbé ní orí òkè ilẹ̀ náà, àwọn ará Kenaani sì ń gbé ẹ̀bá òkun àti ní etí bèbè Jordani.”

  4. Níwọ́n ìgbà tí àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani ń gbé ní àfonífojì, ẹ yípadà lọ́la kí ẹ sì dojúkọ aginjù lọ́nà Òkun Pupa.”

  5. Àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani tó ń gbé lórí òkè sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n, wọ́n bá wọn jà, wọ́n sì lé wọn títí dé Horma.

  6. Nígbà náà ni Balaamu rí Amaleki ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe: “Amaleki ni àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n yóò dahoro níkẹyìn.”

  7. Rántí ohun tí àwọn ará Amaleki ṣe sí i yín ní ọ̀nà nígbà tí ẹ̀ ń jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá.

  8. Nígbà tí àárẹ̀ mú un yín tí agara sì dá a yín, wọ́n pàdé e yín ní ọ̀nà àjò o yín, wọ́n gé àwọn tí ó rẹ̀yìn kúrò, wọn kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

  9. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá fún un yín ní ìsinmi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá yín tí ó yí i yín ká ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run ń fi fún yín láti ni ní ìní, ẹ̀yin yóò sì pa ìrántí Amaleki rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Má ṣe gbàgbé.

  10. Pẹ̀lú ìfi ọwọ́ ṣowọ́pọ̀ ogun àwọn Ammoni àti àwọn ọmọ-ogun Amaleki ní Egloni gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì gba ìlú Ọ̀pẹ tí i se Jeriko.

  11. Nígbà náà ni Saulu kọlu àwọn Amaleki láti Hafila dé Ṣuri, tí ó fi dé ìlà-oòrùn Ejibiti.

  12. Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì gbé ogun ti àwọn ará Geṣuri, àti àwọn ará Gesri, àti àwọn ará Amaleki àwọn wọ̀nyí ni ó sì tí ń gbé ní ilẹ̀ náà, láti ìgbà àtijọ́, bí ó ti fẹ̀ lọ sí Ṣuri títí ó fi dé ilẹ̀ Ejibiti.

  13. Nítorí pé ìwọ kò gbọ́ ohùn Olúwa ìwọ kò sì ṣe iṣẹ́ ìbínú rẹ̀ sí Amaleki nítorí náà ni Olúwa sì ṣe nǹkan yìí sí ọ lónìí yìí.