Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Alexander

5 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń kọjá lọ. Simoni ará Kirene. Òun ni baba Aleksanderu àti Rufusi. Wọ́n sì mú un ní tipátipá pé, kí ó rú àgbélébùú Jesu.

  2. Àti Annasi olórí àlùfáà, àti Kaiafa, àti Johanu, àti Aleksanderu, àti iye àwọn tí i ṣe ìbátan olórí àlùfáà.

  3. Àwọn kan nínú àwùjọ Júù ti Aleksanderu síwájú, wọn si pàṣẹ fun láti sọ̀rọ̀. Ó juwọ́ sí wọn láti dákẹ́ kí ó ba lè wí tẹnu rẹ̀ fun àwọn ènìyàn.

  4. Nínú àwọn ẹni tí Himeneu àti Aleksanderu wà; àwọn tí mo ti fi lé Satani lọ́wọ́, kí a lè kọ́ wọn kí wọ́n má sọ̀rọ̀-òdì mọ́.

  5. Aleksanderu alágbẹ̀dẹ bàbà ṣe mi ni ibi púpọ̀: Olúwa yóò san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.