Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Adjudication at Law

6 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi; nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.

  2. Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà, ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.

  3. Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn bí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́?

  4. Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ, má ṣe tú àṣírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ,

  5. àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójútì ọ́ orúkọ búburú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé.

  6. “Bá ọ̀tá rẹ làjà kánkán, ẹni tí ó ń gbé ọ lọ sílé ẹjọ́. Ṣe é nígbà ti ó wà ní ọ̀nà pẹ̀lú rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò fà ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́, onídàájọ́ yóò sí fá ọ lé àwọn ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, wọ́n a sì sọ ọ́ sínú túbú.