Skip to content

Beth-horon

7 verses

31.8700, 35.1200 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Beth-horon

  1. Olúwa mú kí wọn dààmú níwájú àwọn Israẹli, wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Israẹli sì lépa wọn ní ọ̀nà tí ó lọ sí Beti-Horoni, ó sì pa wọ́n dé Aseka, àti Makkeda.

  2. Bí wọ́n sì tí ń sá ní iwájú Israẹli ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ní ọ̀nà láti Beti-Horoni títí dé Aseka, Olúwa rọ yìnyín ńlá sí wọn láti ọ̀run wá, àwọn tí ó ti ipa yìnyín kú sì pọ̀ ju àwọn tí àwọn ará Israẹli fi idà pa lọ.

  3. Láti òkè tí ó kọjú sí Beti-Horoni ní gúúsù ààlà náà yà sí gúúsù ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó sì jáde sí Kiriati-Baali (tí í ṣe Kiriati-Jearimu), ìlú àwọn ènìyàn Juda. Èyí ni ìhà ìwọ̀-oòrùn.

  4. Kibasaimu àti Beti-Horoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin.

  5. òmíràn gba ọ̀nà Beti-Horoni, ẹ̀kẹta sí ìhà ibodè tí ó kọjú sí àfonífojì Seboimu tí ó kọjú sí ijù.

  6. Jokimeamu, Beti-Horoni.

  7. Ní báyìí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí Amasiah ti rán lọ padà, tí wọn kò nípa nínú ogun gbógun sí àwọn ìlú Juda láti Samaria sí Beti-Horoni. Wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) nínú wọn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ìkógun ńlá.