Nimrod
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Nimrod
Kuṣi sì bí Nimrodu, ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé.
Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa; nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, “Bí Nimrodu, ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa.”
Kuṣi sì bí Nimrodu ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé.
Wọn yóò sì fi idà pa ilẹ̀ Asiria run, àti ilẹ̀ Nimrodu pẹ̀lú idà tí a fà. Òun yóò sì gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Asiria nígbà tí wọn bá gbógun ti ilẹ̀ wa tí wọ́n sì tún yan wọ ẹnu-bodè wa.