Skip to content

Hosea

3 ẹsẹ · 5 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Osee

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Hosea

  1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Hosea ọmọ Beeri wá ní àkókò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah; àwọn ọba Juda àti ní àkókò ọba Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ní Israẹli.

  2. Nígbà tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosea, Olúwa wí fún un pé, “Lọ, fẹ́ àgbèrè obìnrin kan fún ara rẹ, kí ó sì bí ọmọ àgbèrè fún ọ nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin mìíràn, nítorí ilẹ̀ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè púpọ̀ nípa yíyapa kúrò lọ́dọ̀ Olúwa.”

  3. Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé, “Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ‘ènìyàn mi’, àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní ‘àyànfẹ́.’ ”