Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olórí yóò jáde láti Jakọbu yóò sì pa àwọn tó ṣẹ́kù nínú ìlú náà run.”

  2. Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀: “Háà, ta ni ó lè yè nígbà tí Ọlọ́run bá ṣe èyí?

  3. Báyìí ni Israẹli ṣe darapọ̀ mọ́ wọn tí wọ́n sì jọ ń sin Baali-Peori. Ìbínú Olúwa sì ru sí wọn.

  4. Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú gbogbo àwọn olórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, pa wọ́n kí o sì fi wọ́n kọ́ sórí igi ní gbangba nínú oòrùn níwájú Olúwa, kí ìbínú Olúwa lè kúrò ní ọ̀dọ̀ Israẹli.”

  5. Olúwa sì tún sọ fún Mose pé,

  6. “Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà, ti yí ìbínú mi padà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, nítorí tí ó ní ìtara bí èmi náà ti ní ìtara fún iyì mi láàrín wọn, kí ó lè jẹ́ pé èmi ló pa wọ́n run nínú ìtara mi sí wọn.

  7. Nítorí náà sọ fún un pé èmi ṣe májẹ̀mú àlàáfíà mi pẹ̀lú rẹ̀.

  8. Òun àti irú-ọmọ rẹ̀ yóò ní májẹ̀mú láéláé fún iṣẹ́ àlùfáà, nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọ́run rẹ̀ láti fi yẹ́ Ọlọ́run sí, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.”

  9. Olúwa sì tún sọ fún Mose pé,

  10. Lẹ́yìn àjàkálẹ̀-ààrùn Olúwa sọ fún Mose àti Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà pé,

  11. “Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ-ogun ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.” Èyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó jáde láti Ejibiti wá.

  12. àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà.

  13. Olúwa sọ fún Mose pé,

  14. Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.)

  15. Nítorí Olúwa ti sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kíkú ni wọn yóò kú sí aginjù, kò sì sí ẹnìkankan nínú wọn tí kò kú àfi Kalebu ọmọ Jefunne, àti Joṣua ọmọ Nuni.

  16. “Baba wa kú sí aginjù. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí Olúwa, ṣùgbọ́n ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀.

  17. Nígbà náà Mose mú ọ̀rọ̀ wọn wá síwájú Olúwa.

  18. Olúwa sì wí fún un pé,

  19. Tí baba rẹ̀ kò bá ní arákùnrin, fún ará ilé rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ jù ní ìdílé rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀, kí ó lè jogún rẹ̀. Èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.’ ”

  20. Nígbà náà Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sì orí òkè Abarimu yìí, kí o sì lọ wo ilẹ̀ tí mo fún àwọn ọmọ Israẹli.

  21. nítorí nígbà tí ìlú ṣọ̀tẹ̀ níbi omi ní aginjù Sini, tí gbogbo yín ṣe àìgbọ́ràn sí mi láti yà mí sí mímọ́ níwájú wọn.” (Èyí ni omi Meriba ní Kadeṣi ní aginjù Sini.)

  22. Mose sọ fún Olúwa wí pé,

  23. “Jẹ́ kí Olúwa, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, kí ó yan ọkùnrin kan sí orí ìjọ ènìyàn yìí,

  24. láti máa darí wọn, ẹni tí yóò mú wọn jáde, tí yóò sì mú wọn wọlé, gbogbo ènìyàn Olúwa kí yóò dàbí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.”

  25. Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú Joṣua ọmọ Nuni, ọkùnrin nínú ẹni tí èmi wà, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e.