Fò sí àkóónú

Ahaz

37 ẹsẹ · 4 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Achaz

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Ahaz

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ahasi sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Jerusalẹmu ṣùgbọ́n wọn kò mú un wá sínú àwọn isà òkú àwọn ọba Israẹli. Hesekiah ọmọ rẹ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  2. A ti pèsè a sì ti yà sí mímọ́ gbogbo ohun èlò tí ọba Ahasi ti sọ di aláìmọ́ nínú àìṣòótọ́ rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ọba; nísinsin yìí, wọ́n wà níwájú pẹpẹ Olúwa.”

  3. Ìran sí Juda àti Jerusalẹmu èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí ní àsìkò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah àwọn ọba Juda.

  4. Nígbà tí Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah jẹ́ ọba Juda, ọba Resini ti Aramu àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá láti bá Jerusalẹmu jà, ṣùgbọ́n wọn kò sì le è borí i rẹ̀.

  5. Lẹ́yìn èyí, Olúwa sọ fún Isaiah pé, “Jáde, ìwọ àti ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ Ṣeari-Jaṣubu láti pàdé Ahasi ní ìpẹ̀kun ìṣàn omi ti adágún òkè, ní òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀.

  6. Bákan náà Olúwa tún bá Ahasi sọ̀rọ̀,

  7. Ṣùgbọ́n Ahasi sọ pé, “Èmi kì yóò béèrè; Èmi kò ní dán Olúwa wò.”

  8. Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Ahasi kú.

  9. Èmi yóò mú òjìji oòrùn kí ó padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi sọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Ahasi.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀.

  10. Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Hosea ọmọ Beeri wá ní àkókò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah; àwọn ọba Juda àti ní àkókò ọba Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ní Israẹli.

  11. Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Mika ará Moreṣeti wá ní àkókò ìjọba Jotamu, Ahasi, àti Hesekiah, àwọn ọba Juda nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaria àti Jerusalẹmu.

  12. Ussiah ni baba Jotamu; Jotamu ni baba Ahaṣi; Ahaṣi ni baba Hesekiah;