Skip to content
Sefaniah 3:8

Sefaniah 3:8

Ń ṣàfihàn ẹsẹ 8 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
5
Olúwa ni àárín rẹ̀ jẹ́ olódodo; kì yóò ṣe ohun tí kò tọ̀nà. Àràárọ̀ ni ó máa ń mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sí ìmọ́lẹ̀, kì í sì kùnà ní gbogbo ọjọ́ tuntun, síbẹ̀ àwọn aláìṣòótọ́ kò mọ ìtìjú.
6
“Èmi ti ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò, ilé gíga wọn sì ti bàjẹ́. Mo ti fi ìgboro wọn sílẹ̀ ní òfo tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnìkankan kò kọjá níbẹ̀. Ìlú wọn parun tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí yóò ṣẹ́kù, kò sì ní sí ẹnìkan rárá.
7
Èmi wí fún ìlú náà wí pé, ‘Nítòótọ́, ìwọ yóò bẹ̀rù mi, ìwọ yóò sì gba ìtọ́ni!’ Bẹ́ẹ̀ ni, a kì yóò ké ibùgbé rẹ̀ kúrò bí ó ti wù kí ń jẹ wọ́n ní yà tó. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọ́n sì tún ní ìtara láti ṣe ìbàjẹ́.
8
Nítorí náà ẹ dúró dè mí,” ni Olúwa wí, “títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò fi jẹ́rìí sí yin. Nítorí ìpinnu mi ni láti kó orílẹ̀-èdè jọ kí èmi kí ó lè kó ilẹ̀ ọba jọ àti láti da ìbínú mi jáde sórí wọn, àní gbogbo ìbínú gbígbóná mi. Nítorí gbogbo ayé ni a ó fi iná owú mi jẹ run.
9
“Nígbà náà ni èmi yóò yí èdè àwọn ènìyàn padà sí èdè mímọ́, nítorí kí gbogbo wọn bá a lè máa pe orúkọ Olúwa, láti fi ọkàn kan sìn ín.
10
Láti òkè odò Etiopia, àwọn olùjọsìn mi, àwọn ènìyàn mi tí ó ti fọ́nká, yóò mú ọrẹ wá fún mi.
11
Ní ọjọ́ náà ni a kì yóò sì dójútì nítorí gbogbo iṣẹ́ ibi ni tí ó ti ṣẹ̀ sí mi, nígbà náà ni èmi yóò mu kúrò nínú ìlú yìí, àwọn tí ń yọ̀ nínú ìgbéraga wọn. Ìwọ kì yóò sì gbéraga mọ́ ní òkè mímọ́ mi.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options