Rutu 3:2-14
2
Wò ó, Boasi ọkùnrin nì tí ìwọ bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́, tí í ṣe ìbátan wa, yóò wá láti fẹ́ ọkà barle ní ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ ní àṣálẹ́ yìí.
3
Wẹ̀, kí o sì fi ìpara olóòórùn dídùn pa ara rẹ, kí o sì wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó gbé ń pa ọkà, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tí yóò fi jẹ tí yóò sì mu tán.
4
Rí í dájú pé o mọ ibi tí ó sùn sí, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti sùn, lọ kí o ṣí aṣọ ìbora rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè kí o sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ náà. Òun yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe fún ọ.”
5
Rutu sì fèsì pé, “Gbogbo ohun tí ìwọ sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.”
6
Bẹ́ẹ̀ ni Rutu lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un, pé kí o ṣe.
7
Nígbà tí Boasi parí jíjẹ àti mímu tán, tí ọkàn rẹ̀ sì kún fún ayọ̀. Ó lọ, ó sì dùbúlẹ̀ ní ẹ̀yìn ọkà tí wọ́n kójọ. Rutu yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibẹ̀, ó ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè, ó sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.
8
Ó sì ṣe nígbà tí ọkùnrin náà tají ní àárín òru, ẹ̀rù bà á, ó sì yí ara padà, ó sì ṣàkíyèsí obìnrin kan tí ó sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.
9
Ó sì béèrè pé, “Ta ni ìwọ í ṣe?” Rutu sì fèsì wí pé, “Èmi ni Rutu, ìránṣẹ́bìnrin rẹ. Da etí aṣọ rẹ bò mí, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó le è rà mí padà.”
10
Boasi sì wí fún un pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ, ọmọbìnrin mi. Ìfẹ́ tí o fihàn yí ti pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí ó ti jẹ́ wí pé ìwọ kò lọ láti wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bóyá ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà.
11
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìwọ ọmọbìnrin mi, má bẹ̀rù. Èmi yóò sì ṣe ohun gbogbo tí o béèrè fún ọ. Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ ọ́n ní obìnrin oníwà rere.
12
Nítòótọ́ ni mo wí pé èmi jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọ, ṣùgbọ́n ìbátan kan wà tí ó súnmọ́ ọ ju ti tèmi lọ.
13
Dúró síbí títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, bí ó bá sì di òwúrọ̀ tí ọkùnrin náà sì ṣe tan láti ṣe ìràpadà, ó dára kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí Olúwa ti ń bẹ láààyè nígbà náà ni èmi yóò ṣe ìràpadà, sùn sí ìhín títí ilẹ̀ yóò fi mọ́.”
14
Ó sì sùn ní ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀, ṣùgbọ́n ó dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí ẹnìkínní tó le è dá ẹnìkejì mọ̀. Boasi sì sọ fún un wí pé, “Má ṣe jẹ́ kí ó di mí mọ̀ wí pé obìnrin kan wá sí ilẹ̀ ìpakà.”
Settings